Research Access

Thursday, July 5, 2018

YORÙBÁ TOPIc: ÀGBÉYẸ̀WÒ ÌWÉ “OLÚ ỌMỌ” GẸ́GẸ́ BÍ ÀWÒJÌJÌ IPÒ ỌMỌ NÍ ILẸ̀ YORÙBÁ


ÀGBÉYẸ̀WÒ ÌWÉ “OLÚ ỌMỌ” GẸ́GẸ́ BÍ ÀWÒJÌJÌ IPÒ ỌMỌ NÍ ILẸ̀ YORÙBÁ




LÁTI Ọ́WỌ́
OKETADE OLAYINKA SOLOMON
NỌ́NBÀ ÌDÁNÍMỌ̀: 1402/03/04/002



NÍ ÌBÁMU PẸ̀LÚ GBÍGBA ÌWÉ Ẹ̀RÍ TI NCE NÍ ILÉ Ẹ̀KỌ́ MICHAEL ỌTẸDỌLA COLLEGE OF PRIMARY EDUCATION, EPE, LAGOS STATE P.O BOX 1028 LAGOS STATE



ORÍ KÌN-ÍN-NÍ
1.1     ÌFÁÀRÀ
Láì ṣe àní àní gbajúmọ̀ ni ìwé eré oníṣe “olú ọmọ” ní àwùjọ Yorùbá. ẹni tí ó kọ ìwé olú ọmọ ni ọ̀jọ̀gbọ́n Akínwùnmí Ìṣọ̀lá gbájúmọ̀ ònkọ̀wé.
Àwọn Yorùbá bọ̀ wọ́n ní “bí kó bá nídìí obìnrìn kìí jẹ́ kúmólú. Ta ni kò mọ̀ pé obìnrin tí o bá jẹ́ Kúmólú a jẹ́ pé ikú ti pa olú tàbí olórí ilé wọn ní àsìkò tí a bí ọmọbìnrin náà ni?
Ẹfúnróyè Tinúubú jẹ́ obìnrin akọni ní àwùjọ Yorùbá tí Ìṣọ̀lá fi hàn nínú ìwé eré oníṣẹ olú ọmọ.
Aṣíwájú àwọn obìnrin ni a mọ ìyálóde Tinúubú sí ní Èkó àti Ẹ̀gbá ní ìgbà ayé rẹ̀. Sàdédé kọ́ ni ó jẹ́ aṣíwájú obìnrin, ìwà àti ìṣe tí ó ń gbé ṣe ní ọ̀nà kan sí èkejì, agbára àti ẹ̀mí ìgboyà àti àwọn nnkan mìíràn ní, ìgbà ayé rẹ̀ ní ọ́ sọ ó dí1) olú láàárín àwọn ọmọ ní ilẹ̀ Èkó àti Ẹ̀gbá pàápàá jùlọ ilẹ Ẹ̀gbá.

Ohun pàtàkì ti Tinúubú gbé ṣẹ ló mú kí ó yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀dá bíi tirẹ̀. Ohun tí ìtàn mìíràn sọ nípa rẹ̀ ni ó fi hàn nínú ìwé olú ọmọ pé olú ni Tinúubú láàárín ọmọ. Lákotán ìwé olú ọmọ tí Akínwùnmí Ìṣọ̀lá kọ jẹ́ àwòjijì ipò ọmọ ní ilẹ̀ Yoprùbá.

1.2     ỌGBỌ́N ÌWÁDÌÍ
Èyí ni ọgbọ́n tí olùwádìí ló láti jẹ́ kí a mọ òdodo bí ẹ̀rí tí ó kọ sélẹ̀ ṣe lẹ ṣe é fọkàn tán. Ọgbọ́n ìwádìí ní ọgbọ́n tí olùwádìí ń lò láti ṣe ìwádìí lórí kókó ọ̀rọ̀ kan.
Ọgbọ́n tí olùwádìí lò fún iṣẹ́ rẹ̀ yìí ni ọgbọ́n ònkọ̀wé alátínúdá lórí ìwé ìtàn àròsọ kíkà àti eré oníṣe bákan náà.
Ìwádìí tó gba ìrònú jinlè ni ìwádìí yìí tí ó sí fí bí ọ̀nkọ̀wé ṣe ṣàfihàn ipò ọmọ ní ilẹ̀ Yorùbá nínú ìwé yìí (Olú ọmọ). Olùwádìí ka ìwé eré oníṣe Olú-ọmọ láti le sọ bí ipò ọmọ ti ri ní ilẹ̀ Yorùbá. Olùwádìí tún ka àwọn ìwé mìíràn àti pẹ̀lú àfikún ìmọ̀ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ni olùwádìí fi gbé iṣẹ́ yìí jáde.

1.3     SÁBÀBÌ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ
Ohun tí o fa sá bàbí tí olùwádìí fi yàn iṣẹ́ ìwádìí yìí láàyò ni pé, ó fẹ́ mọ bí ipò ọmọ ti rí ní àwùjọ Yorùbá. Olùwádìí sì fẹ́ jẹ́ kí a rántí àwọn olú ọmọ ní ilẹ̀ Yorùbá tí wọ́n ti hùwà akọni ní ilẹ̀ wa kí wọ́n tó di olóògbé àti wipe olùwádìí fé kí àwọn ọ̀nkọ̀wé ní ìmọ́ tó gbòòrò sí i lórí pàtàkì ọmọ ní ilẹ̀ Yorùbá.
Olùwádìí tún fẹ́ kí àwọn òbi ṣe gírí láti rán àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ nípa ìwé kíkà àti iṣẹ́ kíkọ́ kí irúfẹ́ ọmọ bẹ́ẹ̀ le di olú láàárín àwọn ọmọ.

1.4     OHUN ÈLÒ ÌWÁDÌÍ
Àwọn ohun èlò tí olùwádìí lò fún iṣẹ́ ìwádìí rẹ̀ nígbà tí ó ń ṣe ìwádìí yìí ni owó àti ìwé.
Olùwádìí ka oríṣiríṣio ìwé fún iṣẹ́ ìwádìí rẹ̀. ìwé bíi Olú ọmọ tí Akínwùnmí Ìṣọ̀lá kò Olú ọmọ tí D.O Àdìsá kọ, Àtẹ ọ̀rọ̀ tk ọ̀mọ̀wé Olúwakẹ́misọlá Ìdòwú Ọ̀sghọ́ àti Ọ̀gbẹ́ni Ọlátúndé Kọ́mọláfẹ́ kọ. wá gbọ́ tí Dúró Adélékẹ̀ kọ. Àṣà àti ìṣe Yorùbá tí C.L Adéoyè kọ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

1.5     ÀÀLÀ IṢẸ́ ÌWÁDÌÍ
Èyí ni àwọn ibi tí iṣẹ́ ìwádìí yóò tàn dé àtí ibi tí olùwádìí yóò mẹ́nu bà nínú iṣẹ́ ìwádìí náà. Àwọn ibi tk ìwádìí yìí yóò mẹ́nu bà ni, ohun tó fa sábàbí iṣẹ́ ìwádìí yìí, èyí ni ipò ọmọ ní ilẹ̀ Yorùbá.
Àwọn nnkan mìíèan tí a ó rí nínú ìṣẹ́ yií ni oríkí lítírẹ́ṣọ̀ àti ìsọ̀rí lítírésọ̀ ni èdè Yorùbá eré oníṣe àti àwọn ọgbọ́n kíkọ eré oníṣe àpilẹ̀kọ.
Kí ní ọmọ onírúurú ọmọ àti orúkọ ní ilẹ̀ Yorùbá ipò ọmọ ní ilẹ̀ Yorùbá, àhunpọ̀ ìtàn ìwé olú ọmọ ipò ọmọ ní ilẹ̀ Yorùbá nínú ìwé olú ọmọ.
Àwọn nnkan mìíràn tí a ó mẹ́nubà ni oríkí lítíréṣọ̀ àti ìsọ̀rí lítíréṣọ̀ ní èdè Yorùbá. Ìtunmò eré oníṣe àti àwọn ọgbọ́n kíkọ eré oníṣẹ àpilẹ̀kọ ta a ni a ń ot ni ọmọ àti onírúurú ọmọ pẹ̀lú orúkọ ní ilẹ̀ Yorùbá.
Ìpò ọmọ ní ilẹ̀ Yorùbá àhunpọ̀ ìtàn ìwé olú ọmọ àti ipò ọmọ ní ilẹ̀ Yorùbá nínú ìwé olúọmọ. àwọn nnkan wọ̀nyìí ni a ó mẹ́nubà nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí.

                 

      Bank: ACCESS BANK PLC
   Account Name: ALELAMOLE PRECIOUS H. 
   Account Number: 0732881883
   Account Type:SAVINGS
   Amount: ₦3,000
INSTRUCTIONS AFTER PAYMENT.
After payment, send the following details to 08133742738 or 08056089202 or e-mail your payment details to omotopreciousventures@yahoo.com

Payment Details We Expect From You.
  • Depositor’s name
  • ATM location (for ATM transfers)
  • Bank used in making the payment (for ATM transfers and Bank deposits)
  • Amount paid
  • The Requested Project topic
  • A functional e-mail address
Projects are sent in MS word format within 30 minutes of payment confirmation.


   For questions and complaints call: +2348133742738 or +2348056089202


1 comment:

leave your message

advertisement