ÀGBÉYẸ̀WÒ ÌLÀNÀ ORIN ỌRLANDÒ Ọ̀WỌ̀H
LÁTI
ỌWỌ́
JEGEDE
OLARENWAJU
NọNBÀ ÌDÁNIMỌ̀: 1402/01/06/005
IṢẸ́
ÀPILẸ̀KỌ TI Ẹ̀KA ÈDÈ YORÙBÁ FÚN ÌKÀWÉ GBOYÈ ÌWÉ Ẹ̀RÍ ÀKỌ́KỌ́ NÍNÚ ÌMỌ̀ ÌJÌNLẸ̀
ÈDÈ YORÙBÁ TI MICHAEL ỌTẸDỌLA COLLEGE OF PRIMARY EDUCATION (MOCPED) NÍ ÌLÚ
Ẹ̀PẸ́, NÍ ÌPÍNLẸ́ ÈKÓ.
OṢÙ
ỌPẸ ỌDÚN 2017
IJẸ́RÍÌSÍ
ÀTI ÀTỌ́NISỌ́NÀ
Èyí ni ìjẹ́ríìsì pé iṣẹ́ àkànṣe yìí jẹ́
ti arakùnrin Jegede Olarenwaju ti ẹ̀ka Èdè Yorùbá pẹ̀lú Nọ́nbá idánimọ̀: 1402/01/06/005 ti Ekiti State University
Ẹ̀pẹ̀ ní ìpínlẹ̀ ẹ̀kó, ni o ṣe iṣẹ́ àpilẹ̀kọ yìí ni abẹ́ alábòójútó Iyá Àfin
O.T. Ọlábọ̀dé.
……………………….. ………………………..
ÌYÀ-ÀFIN
ỌLÁBỌ̀DÉ DÈÈTÌ
ÌDÚPẸ́
Yorùbá bọ́ wọ̀n ni “ẹni tí a ṣe lore tí
o dupẹ́, bìí ọlọ́ṣà kónilẹ́rù lọ nipé “bí ọmọdé bá dúpẹ́ oore àná, á rí òmíràn
gbá”. Èyí ló mú mi dúpẹ́ lọ́wọ́ Olódùmarẹ̀, ọba to mọ mì, tó mọ́ mí.
Mo dúpẹ́ fún ohun gbogbo tí Ọlọ́run ṣe
fún mí, fún okun àti agbára tí ó fún mí láti ìgbà tí mo tí bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ mi yìí,
tí ó sì mú mí parí rẹ́ pẹ̀lú ayọ̀ àti àlààfíà iyín àti fún orúkọ rẹ̀ lókè
ọ̀run.
Ọ̀pẹ́ pàtàkì lọ́wọ́ gbogbo àwọn olùkọ́
mi láti ilé ìwé alàkọbẹ́ẹ̀rẹ̀ títí ilè ẹ̀kọ́ giga ti mi wà yìí ti ilé ìwé
Michael Ọtedọla College of Primary Education (MOCPED) Ilú Ẹ̀pẹ́, ní ìpínlẹ̀ èkó
fún ìmọ̀ràn wọ́n lórí ìdàgbàsóké ẹ̀kọ́ mi, ni pàtàkì júlọ ìyá aafin O.T. Ọlabọde
tí wọ́n jẹ́ aláboojútó àti olùtọ́nísọ́nà fún mi nígba ti mo ń ko ìwé àpilẹ̀kọ
yìí. Mo ṣe ládùúrà pé, ìwájú ni ọ̀pá ẹ̀bìtì yín yóò máa ré sí o. Ẹ ò rí ṣubú
dàánú, ẹ ó ni rín lọ́jọ́ tébi bá n pa ọ̀nà (Àmín).
Mo tún dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn òbí mí tí wọ́n
làkàkà láti rí pé mo ṣe àṣeyọrí lórí ẹ̀kọ́ mi, pàápàá júlọ ìyá mi, ìyá aafin
Idowu Salami, abiyẹmọ tòótọ́, ìyá lọjọ ìṣoro, àwọn Yorùbá bọ̀, wọn ni bi kò ba
si igi lẹ́yìn ọgbà, wi wo ni wó, mo dúpẹ́ gidigidi gan lọ́wọ́ mama mi, mo gba
ládùúrà pe iṣu ọmọ a jìna fún yín jẹ (Àmín).
Ọpẹ́ mí tún lọ́ sì ọ̀dọ̀ olóòlùfẹ́ mi
láti fi ìmọ̀ ore àti ìdúpẹ́ mi hàn sí, Ọ̀gbẹ́ni Ọlọrunfẹmi Otuyẹmi nítorí pé ó ṣe
gúdúgúdú méje àti yàáyàá mẹfa, kí Ọlọ́run bá mi ràn lọ́wọ́.
Ní ìkọ́tán ọpẹ́ mi tún lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn
ọ̀rẹ́ mi, fún ìrànlọ́wọ́ wọn lọ́nà kan tàbí òmíràn àti fún àṣeyege iṣẹ́ yìí, Ọlọ́run
yóò máa ràn yín lọ́wọ́. Yorùbá bọ̀, wọ́n ní eégun nlá ni gbẹ̀yìn ìgbàlẹ̀ léèkan
síí mó tún dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run Ẹlẹ́dàá mi, oyigiyigi, Ọba oníbú ọrẹ, Atẹrẹrẹ
kárí ayé, Káábiyesi o, títí ayé ni n o máa dúpẹ́.
ORÍ KÌN-ÍN-NÍ
1.0 ÌFÁÀRÁ
Yorùbá
bọ̀, wọ́n ni, bí kò nìdìí, obìnrin kan kìí jẹ́ kúmọ́lú ìdí nìyí tí mo fi ń kọ iṣẹ́
ìwádìí mí yìí lórí gbajúmọ̀ olóògbé olórin Ọládìípọ̀ Owomọyela tí gbogbo ayé
mọ̀ sí Orlando Ọwọh, ẹni tí ó máa ń kọ irúfẹ́ orin tí òun alára ń pè ní African
Kẹnnerica.
Nínú
iṣẹ̀ ìwádìí mí yìí, a óò ni ànfààní láti mọ irúfẹ́ orin tí ó wá láàárìn àwọn
Yorùbá, ìpò orin Orlando Ọwọh láàárín orin amúlùúdún, eléyìí tí yóò sì fún ẹni
tí kò tilẹ̀ mọ̀ nípa rẹ̀ ni ìmọ̀ pé orin rẹ̀ kò ṣe é fọwọ̀ rọ́ sẹ́yìn láàárín
àwọn olórin bi tirẹ̀ yóòkù àti pé ọ̀gá sin í láwùjọ́ pèdèpèdè. A óò tún ní
ànfààní láti kà nípa ìwúló àwọn orin amúlùúdùn láwùjọ Yorùbá.
Síwájú
sí, a ní anfààní láti kà nípa bí Orlando Ọwọh ṣẹ máa ń ṣọwọ́ lo èdè nínú orin
rẹ̀. Aà tí tún láti sọ nípa èrò àwọn ènìyàn nípa orin tí Orlando Ọwọh ń kọ̀.
Níbí
yìí ni á óò ti rí onírúurú èrò ti àwọn ènìyàn ni sí orin rẹ̀ nípa dídára tàbí
áìdára.
Bákan
náà ni a ọ́ọ̀ tún ní ànfààní àti tẹ̀síwájú nípa ọjọ́ ìwájú orin Orlando Ọwọh
gẹ́gẹ́ bí òwe Yorùbá kan tí ó sọ wí pé ìgbà kò lọ bí òréré, ọjọ́ kìí tọ́ lọ bi
ọ̀pá ìbọn tótó ṣe bí òwe àẹ́ọn àgbà. Níbí yìí ni a óò tin í òye àti àfojúsùn ọjọ́
ìwájú orin Orlando Ọwọh.
1.1
KI NI LITIRESO
Litireso je ise-ona ti o n se afihan iwa
isesi, ihuwasi ati asa kan. Loitireso je irisi awujo ti a fi ewa ede gbe kale
eyini ohun ti o yato si ohun ti kii se litireso.
Litireso je atinuda ti a gbe kale lati se
afihan awon ohun ti o n sele lowolowo tabi awon ohun to ti sele seyin seyin ni
awujo bi litireso se n se akiyesi ayika ni o n se afihan bi awujo ti a furugbin
re se ri. Litireso ma a ri pe akiyesi si ohun auyangan ati awon ohun amusogo ti
o bori iwa aito to kun awujo fofo.
Orisirisi
alaye ni awon ojogbon ti menu ba lori nnkan ti litereso je. Fun apeere,
Babalola (1969) so pe ohun ti o n je “Litireso ni akojopo oro ni ede kan tabi
omiran. Iru ijinle oro to jasi ewi, arofo, itan alo, iyanju, iroyin tabvi ere
onitan ti a mo si ere onise tabi ere akonilogbon lori itage. O tun pe litireso
ni akosile ti o n fi bi aye ti ri han. Ki litireso to di kiko sile tabi tite
jade ninu iwe, opolopo igba ni o je wi pe litireso ni ise ona ti a fi oju inu
wo ti o jinle ati asayan oro to muna doko ni gbigbe jade lati fi se alaye.
Fasakin (1992) nigba ti o ye ise Babalola
(1969) ati Oginni (1981) wo, o pe litireso ni akojopo ijinle oro ni ede kan
tabi omiran. Inu ijinle oro naa le ewi, arofo itan, alo ere onitan tabi onise
ati bee bee lo.
O tesiwaju lati so pe a le fi litireso
salaye eniyan ati awujo re. bi eniyan ba ro litireso ni arojinle o je nnkan
gidi ti o si wulo lawujo.
Siwaju si awon
onkowe bii De Bonald ati Taine ti so asoye oro pe afihan awujo ni litireso so
je, won toka si pe bi dingi tii je afoju eni han bee ni litireso je fun awujo.
Ogunsina (1988) so isonisoki ohun ti
litireso je nigba ti o salaye pe:
Afihan
awujo ni litireso je…….
Bi
dingi ti o je afoju eni han
Ni
litireso je fun awujo
Ki
se pe litireso n je fi awujo han
Nikan,
atupale awujo lo n se
Ilesanmi (1990) ati Kenhinde (1988) mu u
dani loju pe:
Litireso
ni ilana ti a n gba so faye gbo ohun ti a gbe kale lona ara tabi lona
alumokoroyi lopo igba lai daruko pato awon eni ti oro kan gan-an. Sugbon ti
asayan oro ijinle pelu ohun to bu ewa kun ohun ti a n so maa n saba je eni to n
se agbekale naa logun.
Ise ti litireso n se ni ki o dani laraya, ko
koni logbon ko si kilo iwa (Awe, 2004). Ti awon eniyan awujo ba farabale ti won
ronu jinle, ede litireso yoo ye won, yoo
si tu gbogbo koko ti ehun oro litireso ka.
1.1.1
ISORI LITIRESO
Ona meji ni a le pin
litireso Yoruba si, akoko ni litireso alohun, ekeji si ni litireso apileko,
bakan naa ni a le pin litireso alohun si isori meta
Alo apamo
Ewi alohun
Alo onitan
Bi litireso alohun
se je eya kan lara litireso Yoruba Yoruba ti o pin si isori meta meta bee ni
litireso apileko pin si isori meta.
Ewi apileko
Ere onitan tabi ere onise
Itan aroso
Kii se dandan ni ki
litireso je akosile gbogbo awon ero ati imo ijinle to ti wa ni opolo awon
eniyan awujo sorosoro ni litireso je. Eyi ti o wa ninu opolo ti a ko ko sile
lati inu opolo wa ti a si se atejade re ni apileko
Bi o tile je wipe opolopo litireso
alohun ni a ti n ko sile ti a si n te jade, sugbon eyi ko so won di apileko
rara. Nitori pe opolopo litireso apileko ti a ko sile ni a le fi ohun orisirisi
ti o ba wu wag be e jade bi I ohun ijale, iyere ifa, abbl ti eyi ko si so won
di litireso alohun.
Ti a ba wo akole ise yi a o ri I pe
litireso apileko ni o da le lori. Isori ti akole naa wa ni ere onitan ti a tun
mo si ere onise.
1.2 KÍN
NI ORIN?
Onírúurú
àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ni wọ́n ti fún orin ní oríkì ṣùgbọ́n ojú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní
olúkúlúkù wọn fi wo orìkì orin. Ọ̀nà tí wọ́n sì gbé oríkì yìí gbà kò jọ ara wọn,
ọ̀nà kan ò wọjà ni. Díẹ̀ nínú àẹ́ọn tí ó ti gbìyànjú láti fún orin ní oríkì ni.
“
C.M Bówa (1962) tí ó sọ pé:
“Ohun
tí a lè pè ní orin ni nnkan tí a ròò lọ́kàn ti a sì
Kọ
jáde nígbà tí ó dàbí ẹni pé a àwọn nnkan tó ṣàjòjì
Tàbí
ju agbára wa lọ. nígbà tí a ro pè ọ̀rọ̀ ẹnu lásán kò
Ni
lè ṣàlàyé bí nnkan náà ṣe ká wa lára to”.
Ti
a bá wo oríkì yìí, a ní láti ri pé ó fi síbìkan, nítorí pé kìí ṣe orin nìkan ní
ènìyàn fi máa ń gbé èrò ọkàn jáde, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀nà ti a lè gbàgbé
èrò ọkàn jáde.
“Olúkoju
E.O (1982) ni tirẹ̀ sọ wí pè:
“Ọ̀kan
lára ọ̀nà tí Yorùbá ń gbà láti lo ohun wọn lọ́nà àrà láti fi èrò inú wọn hàn ni
orin jẹ́. Orin dàbí ọ̀rọ̀ tí a sọ tí ó yá nílẹ̀ ju ìgbà tí à ń sọ̀rọ̀ lásàn lọ.
Tí
a bá wo oríkì yìí, a ó rí wí pé nígbà tí ènìyàn bá ńkọ ọ́ nítorí pé àwọn orìn
mìíràn wà tí ó jw wí pé wọ́n lọ nílẹ̀ ju ọ̀rọ̀ ẹnu lọ.
Nínú
ìwé ewì Princeton (1993) Princeton (Encyclopedia of poetry and poetics) náà ṣàlàyé
wí pé
“Orin
wà gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí ó ní orísun èyí tí a kò lè yapa kúrò nínú ewì, àwọn
Yorùbá nítorí pé ó n mú àròjìnlẹ̀ sínu ọkàn àwọn ẹni tí ó ń gbọ́ ọ yálà ó ni
ilù tàbi kó ni, orin ò lè gbé ohun dídùn jáde pẹ̀lú ìlù.
Nnkan
ti mo rí sí oríì yìí ni wí pé kìí ṣe gbogbo orin ni a lè lu ìlù sí, kìí sìí ṣe
gbogbo rẹ̀ náà ni ó dùn gbọ́ ọ́ lẹ́ti.
Pẹ̀lú
gbogbo ìwádìí ti mo ṣe lórí ìtumọ orin, tí mo sì ní àwọn onirùurú orìkí tí àwọn
onímọ̀ fún orin ni ó jẹ́ kí èmi náà ní òye orúkọ orin àti wí pé ìtùmọ́ tí orin
ni sí èmí gan-an- alára.
Ni
èrò témí, orin ni àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tàbí àpapọ̀ ìrò tí ó máa ń dùn gbọ́ ọ́ léti ẹnití
ó ń gbọ.
Orin
yìí náà ni ènìyàn máa ń lò láti gbé èrò ọkà jáde, orin yìí kò sì ní ìgbà ka
pàtó tí Yorùbá máa ń kọ́.
1.3 IPÒ
TÍ YORÙBÁ TO ORIN SÍ
Yorùbá
kò kóyán orin kéré nínú gbogbo igbòkègbodò wọn, kò sí ìṣẹ̀ yòówù ti Yorùbá kìí
ni orin fún. Kọọ̀rinkọrin ni àwọn Yorùbá nínú àwọn orin wọ tí ó kún fún ọ̀rọ̀
bi ewì, wọ́n á máa sọ ìtàn dídùn nípa ayé àtijọ́, bí òde ṣe rí lọ́wọ́ àti ìrètí
nípa ọjọ́ ọ̀la.
Gẹ́gẹ́
bí Bọla Idowu (1962:35) ṣe sọ, kò yà wá lẹ́nu nígbà tí ilé-iṣw rédíò ìpìnlẹ̀
Ọ̀yọ́ bá ń kọrin pé Yorùbá ló ni orin, orin náà ló sì ní wọ́n. Wọ́n á wí báyìí
pé:
“Àwa la lorin
Orin náà ló niwá
Orin ò lè báwa lójij
Àwa la lorin
Orin náà ló niwá”
Wàyí
o, ẹ jẹ́ kí a wo oríṣíríṣí ìṣẹ̀lẹ̀ tí a lè lo orin fún ní ilẹ̀ Yorùbá. Gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀
ti ó bá ń ṣẹlẹ̀ láàrìn àwọn Yorùbá ni wọ́n máa ń ni orin tí ó bamu gẹ́gẹ́ bi a
sì ti ṣe mọ̀ wí pé orin ni a máa ń lò láti gbé èrò ọkàn wa jáde bí oríkì rẹ̀ ti
sọ.
Àpẹẹrẹ
“Ta ló nàá o
ẹyẹ ni o
sọ̀kò bá o
ó sá lọ o
Eléyìí
jẹ́ orin tí ó ń fi ìrétí wọn hàn lórí ọjọ́ ìwájú wọn tàbí tí ọmọ wọn. orin tí
àwọn abiyamọ tún máa ń kọ tí ọmọ bá kọ̀ tí kò dákẹ́ mọ́ nìyí;
“Ó tó ọmọ mí, ótó
ṣèbi mo tí bẹ̀ ó lẹ́ẹ̀kan
o má si rorò pọọ
ó jọ pẹ̀
o lá ṣejù lọ́wọ́
1.3.3 ORIN
ÌTÙNÚ
Àwọn
Yorùbá tún máa ń lo orin láti fit ù ènìyàn nínú. Irú ori yìí máa ń ṣíṣẹ́ ìwáàsù
fún olùgbọ̀, ó si tún máa ń sọ fún olùgbọ́ rẹ̀ wí pé kí ó ní ìrètí.
Àpẹẹrẹ
“Bóti wù kó gùn kó le tó
Ó ń sọmọ olókùú bẹ́ẹ̀ ni
A ó ni sin-in pẹ̀lú òkú rẹ̀
Wàá bori ìṣòro dandan
1.3.4 ORIN
Ẹ̀HÓNÚ
Ni
ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, dípò kí Yorùbá lo ọ̀rọ̀ ẹnu lásán láti ẹ̀hónú hán, wọ́n a máa
lo orin.
Bí
àpẹẹrẹ, bi àwọn òbí ọmọbìnrin bá fi fún ẹnikan ti inú rẹ̀ kò dùn mọ́, ó fi
ẹ̀hónú rẹ̀ hàn nipa fifi orin gbée jáde báyìí pé:
“Ẹni ẹ ni n fẹ́
Ẹni ẹ ni n fẹ́
Bóyá bóyá óyá
Ẹni ẹ torì ẹ̀ nà mí
Bóyá bóyá óyá
Ni n ó fẹ
Àwọn
ará ìlú tún máa n fi ẹ̀họ́nú wọn hàn. Àpẹẹrẹ eléyìí ni wí pé ìgbà tí wọ́n ni kí
àwọn obìnrin san owó orí ni ìlẹ̀ Yorùbá orin tí àwọn obìnrin kọ láti fi ẹ̀hónú
wọn hàn niyi.
“Gọngọ
a á sọ ò o
Gọngọ
a á sọ ò o ọba wa
Eni
kọ́kùnrin sanwó orí
A
ò kọ̀ èwo tún ni tobìnrin
Gọngọ
a á sọ ò o”
Bank: ACCESS BANK PLC
Account Name: ALELAMOLE PRECIOUS H.
Account Number: 0732881883
Account Type:SAVINGS
Amount: ₦3,000
Amount: ₦3,000
INSTRUCTIONS AFTER PAYMENT.
After payment, send the following
details to 08133742738 or 08056089202 or e-mail your payment details
to omotopreciousventures@yahoo.com
Payment Details We Expect From You.
- Depositor’s
name
- ATM
location (for ATM transfers)
- Bank
used in making the payment (for ATM transfers and Bank deposits)
- Amount
paid
- The
Requested Project topic
- A
functional e-mail address
Projects are sent in MS word format
within 30 minutes of payment confirmation.
For questions and complaints
call: +2348133742738 or +2348056089202
No comments:
Post a Comment
leave your message